Alágbára Àgbàrá n gbagbára lówó alágbára,
àìfiyèsí Àmòtékùn n fitékòkò d'eran Àgbò,
Alágbára le sapá k'ípá pin,
Bee l'àmòtékùn lejà raburabu dóòlà obè.
Amo baati waye paori beena laari,
Ologbon kan o ta koko omi seti aso,
Omoran kan o moye yepe ile,
Kadara o seeye, akosile o se yipada.
Beena sa loro ife ri,
Ama kánimólé bii gbéwiri,
Ama hanni leemo bi tolósà,
Asi tun dunmoni bi afara oyin.
Ife ngbekun,
Ife ngberin,
Ife ngboni ririri bi kayepare,
Asitun gunni galegale bi pe ile osi mo.
Ayanmo nife,
Akosejaye l'abanisaye,
..........................
Won leniafe lamo,
Sugbon mo meni to femi,
Ajoke mi owon, mo nife re,
osi nife mi pelu.
Lase eledua, Ife wa o ni bomi lo....
This poem has not been translated into any other language yet.
I would like to translate this poem